Ó wu Olódùmarè ló dirí ẹwà fákùkọ;
Ó wu Adẹ́dàá ló pé tọ̀kín lẹ́wà;
Ó wu Adẹ́dàá ló ṣe wá ní mùsùlùmí;
Ẹlédùmarè tún wa ṣe papanbarì,
Ó dé wa ládé ìbòrí,
Adé ẹ̀sìn,
Adé orí ọ̀kín ò kúkú jọ tẹyẹ-kẹ́yẹ.
Adẹ́dàá fún wa lẹ́wà;
Ó tún wa fìbòrí kẹ́wà fún wa;
Ó sọ wá dawẹ́lẹ́wà oníwàrere;
Àwa kì í ṣe
aborí-má-bòwà;
A borí, a bòwà;
A tún wá fìwà kẹ́wà wa,
A fìwà kẹ́sìn.
Ẹní bá ti rí oyún inúu Fùlání;
Á ti mọ̀ pé Mọ̀látò ni ó fi bí;
Ẹní bá ti rí mi pẹ̀lú ìbòrí tí; Adẹ́dàá fi dé mi ládé;
Tì mọ̀ pé mùsùlùmí ni mí;
Nítorí a kì í júwe ẹnu fáfọ́jú;
Bẹ́ẹ̀ ni,
Àmì ìdánimọ̀ mi ni ìbòrí tÁdẹ́dàá fi dé mi ládé.
Mo tilẹ̀ gbọ́ pé;
Bí a ti ń dá bí ẹdun láwùjọ;
Tí a sì ń rọ̀ bí òwè nílùú;
Àwọn kan, àwọ̀n kàn;
A máa wí pé;
Ṣé pé àwọn àlàájà náà dáńtọ́?
Ṣé pé wọ́n tó gban̄gbá sùn lọ́yẹ́?
Họ́wù!
Orí la bò,
A ò fi ìbòríi wa bo ọpọlọ wa mọ́lẹ̀;
A gbóunjẹ fẹ́gbẹ́;
A gbàwo bọ̀;
A dáńtọ́;
A kúnjú òṣùwọ̀n.
Ẹ dẹ́kun àti máa fojú rénà wa;
Nítorí adé tí Olódùmarè fi dé wa ládé;
Má fi sùúrù mi pe òmùgọ̀;
Bémiì rẹ bá ní gbọ́n-mi-sí-i-omi-ò-tó-o,
Èmi ni kí o bá nájà;
Má fi tìbòríì mi kún un;
Má fi tẹ̀sìn mi kún un.
Má fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ mí,
Nítorí pé a ti ri pé mo dádé;
TÁdẹ́dàá fi ṣẹ̀ṣọ́ fún mi;
Ìdánimọ̀ mi ni ìbòríì mi;
Bí mo bá yọ lókèrè;
A sì dàbíi pé òṣùpá ọjọ́ kẹrìnlá ló yọ;
Agbára ńlá ni ìbòrí tÁdẹ́dàá fi dé mi ládé.
Agbára ẹ̀sìn,
Agbára ògo,
Agbára ìfẹ́,
Agbára àlàáfíà,
Agbára ìfẹ́,
Agbára ìgbàgbọ́,
Nítorí náà; má fojú bíńtíi mi;
Nítorí pé adé orí ọ̀kín mi, kò jọ tẹyẹ-kẹ́yẹ;
Ìdánimọ̀ mi ni ìbòríì mi.